Matthew 16:1-4

Bíbéèrè Fún Ààmì

1 aÀwọn Farisi àti àwọn Sadusi wá láti dán Jesu wò. Wọ́n ní kí ó fi ààmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run.

2Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’ 3Ní òwúrọ̀, ‘Ẹ̀yin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ ààmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ ààmì àwọn àkókò wọ̀nyí. 4Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè ààmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkankan ní ààmì bí kò ṣe ààmì Jona.” Nígbà náà ni Jesu fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

Copyright information for YorBMYO